Onigbagbo E Bu Sayo (Yoruba Hymns)

Onigbagbo E Bu Sayo

1. Onigbagbo e bu sayo!
Ojo nla loni fun wa
Korun fayo korin kikan,
Kigbo atodan gberin
E ho! E yo!
Okun atodo gbogbo.

2. E jumo yo, gbogbo eda,
Laye yi ati lorun,
Ki gbogbo ohun alaaye
Nile, loke, yin Jesu
E fogo fun
Oba nla ta bi loni.

3. Gbohun yin ga, “Om’Afrika”
Eyin iran Yoruba;
Ke “Hosanna” lohun gooro
Jake jado ile wa.
Koba gbogbo,
Juba Jesu Oba wa.

4. E damuso! E damuso!
E ho ye! Ke si ma yo,
Itegun Esu fo wayi,
“Iru-omobinrin” de.
Halleluyah!
Olurapada, Oba.

5. E gbohun yin ga, Serafu,
Kerubu, leba ite;
Angeli ateniyan mimo,
Pelu gbogbo ogun orun.
E ba wa yo!
Odun idasile de.

6. Metalokan, Eni Mimo
Baba Olodumare
Emi Mimo, Olutunnu,
Jesu, Olurapada,
Gba iyin wa
‘Wo nikan logo ye fun.

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *