Home >> Yoruba Hymns

E sin Oluwa ninu ewa iwa mimo (Yoruba Hymns)

1. E sin Oluwa ninu ewa iwa mimo
E wole k’e si korin iyin Re
Wa sodo Re pelu ‘rele ati igboran
E wole k’e si juba, Oko Re

2. Eko gbogbo aniyan okan nyin le lowo
Y’o ru gbogbo re, O nsaniyan nyin
Y’o tu o ninu, y’o si dahun adura re
Y’o s’amona re, y’o se b’O ti to

3. Mase beru lati wo ‘nu ile Oluwa
O npe talaka, O npe oloro
Mura lati gba oto at’ife Re s’okan
Eyi ni ore, t’o se ‘tewogba

4. Ebo Olorun ni irobinuje okan
Iru ebo yi On ko ni kegan
Gbogbo ibanuje wa On o so di ayo
Y’o fun wa, n’ireti at’igbagbo

5. E sin Oluwa ninu ewa iwa mimo
E wole k’e sin korin iyin Re
Wa sodo Re pelu ‘rele ati igboran
E wole k’e si juba Ooko Re

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *