L’oju Ale Gbata’Orun Wo (Yoruba Hymns)

L’oju Ale Gbat’ Orun Wo

1. L’ oju ale gbat’ orun wo
Nwon gbe abirun w’ odo Re
Oniruru ni aisan won
Sugbon nwon f’ ayo lo ‘le won

2. Jesu a de l’ oj’ ale yi
A sunmo t’ awa t’ arun wa
Bi a ko tile le ri O
Sugbon a mo p’ O sunmo wa

3. Olugbala wo osi wa
Omi ko san mi banuje
Omi ko ni ife si O
Ife elomi si tutu

4. Omi mo pea san laiye
Benin won ko f’ aiye sile
Omi l’ ore ti ko se ‘re
Beni nwon ko fi O s’ ore

5. Ko s’ okan ninu wa t’ o pe
Gbogbo wa si ni elese
Awon t’ o si nsin O toto
Mo ara won ni alaipe

6. Sugbon Jesu Olugbala
Eni bi awa n’ Iwo ‘se
‘Wo ti ri ‘danwo bi awa
‘Wo si ti mo ailera wa

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *