Fi Iyin Fun Jesu, Olurapada Wa (Yoruba Hymns)

Fi Iyin Fun Jesu, Olurapada Wa

1. Fi iyin fun Jesu, Olurapada wa,
Ki aye k’okiki ife Re nla ;
Fi iyin fun ! eyin Angeli ologo,
F’ola at’ogo fun oruko re,
B’olu’agutan, Jesu y’o to omo Re
L’apa Re l’o ngbe won le l’ojojo
Eyin eniyan mimo ti ngb’oke Sion
Fi iyin fun pelu orin ayo

2. Fi iyin fun, Jesu Olurapada wa,
Fun wa, O t’eje Re sile, O ku
On ni apata, ati reti ‘gbala wa,
Yin Jesu ti a kan m’agbelebu;
Olugbala t’O f’ara da irora nla
Ti a fi ade egun de lori
Eniti a pa nitori awa eda
Oba ogo njoba titi laelae.

3. Fi iyin fun, Jesu Olurapada wa
Ki ariwo iyin gba orun kan
Jesu Oluwa njoba lae ati laelae,
Se l’oba gbogb’eyin alagbara
A segun iku; fi ayo royin na ka
Isegun re ha da, isa oku?
Jesu ye ko tun si wahala fun wa mo
‘tori O l’agbara lati gbala. Amin.

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *