Wa Ba Mi Gbe (Yoruba Hymns)

Wa Ba Mi Gbe

1. Wa ba mi gbe, ale fere le tan
Okunkun nsu, Oluwa ba mi gbe;
Bi oluranlowo miran ba ye
Iranwo alaini, wa ba mi gbe

2. Ojo aye mi nsare lo s’opin
Ayo aye nku, ogo re nwomi
Ayida at’ibaje ni mo n ri
‘wo ti ki yipada, wa ba mi gbe

3. Ma wa l’eru b’Oba awon oba
B’oninure, wa pelu ‘wosan Re?
Ki Ossi ma kanu fun egbe mi
Wa, ore elese, wa ba mi gbe.

4. Mo nfe O ri, ni wakati gbogbo
Kilo le swgun esu b’ore Re?
Tal’o le se amona mi bi Re?
N’nu ‘banuje at’ayo ba mi gbe

5. Pelu ‘bukun Re, eru ko ba mi
Ibi ko wuwo, ekun ko koro,
oro iku da? ‚segun isa da?
Un o segun sibe, b’iwo ba mi gbe.

6. Wa ba mi gbe, ni wakati iku,
Se ‘mole mi, si toka si orun
B’aye ti nkoja, k’ile orun mo
Ni yiye, ni kiku, wa ba mi gbe. Amin.

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *