Wa S’adura Oorọ (Yoruba Hymns)

Wa S’adura Oorọ

WA s’adura oorọ,
Kunlẹ k’a gbadura;
Adura ni ọpa Kristiani,
Lati b’Ọlọrun rin.

Lọsan, wolẹ labẹ,
Apat’ ayeraye;
Itura ojiji Rẹ dun,
Nigba t’orun ba mu.

Jẹ ki gbogbo ile,
Wa gbadura l’alẹ;
Ki ile wa di t’Ọlọrun,
Ati ‘bode ọrun.

Nigba ti o d’ọganjọ,
Jẹ k’a wi l’ẹmi, pe,
Mo sun, sugbọn ọkan mi ji
Lati ba Ọ sọna.

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *