Oluwa Mi Mo Njade Lo (Yoruba Hymns)

Oluwa Mi Mo Njade Lo

1. Oluwa mi mo njade lo
Lati se ise ojo mi
Iwo nikan l’ emi o mo
L’oro l’ ero, ati n’ ise

2. Ise t’o yan mi l’ anu re
Je ki nle se tayotayo
Ki nr’ oju Re ni ise mi
K’ emi si le f’ ife Re han

3. Dabobo mi lowo ‘danwo
K’ o pa okan mi mo kuro
L’ owo aniyan aiye yi
Ati gbogbo ifekufe

4. Iwo t’oju Re r’ okan mi
Ma wa low’ otun mi titi
Ki nma sise lo l’ase Re
Ki nf’ ise mi gbogbo fun O

5. Je ki nreru Re t’o fuye
Ki nma sora nigbagbogbo
Ki nma f’ oju si nkan t’orun
Ki nsi mura d’ojo ogo

6. Ohunkohun t’ o fi fun mi
Je ki nle lo fun ogo Re
Ki nfayo sure ije mi
Ki mba O rin titi d’ orun

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *