Iwo To Fe Wa La O Ma Sin Titi (Yoruba Hymns)

Iwo To Fe Wa La O Ma Sin Titi
1. Iwo to fe wa la o ma sin titi
Oluwa Olore wa
Iwo to n so wa n’nu idanwo aye
Mimo, logo ola re

[Egbe]
Baba, iwo l’a o ma sin
Baba, iwo l’a o ma bo
Iwo to fe wa l’a o ma sin titi
Mimo l’ogo ola re.

2. Iwo to nsure s’ohun t’a gbin s’aye
T’aye fi nrohun je o
Awon to mura lati ma s’oto
Won tun nyo n’nu ise re.

3. Iwo to nf’agan lomo to npe ranse
Ninu ola re to ga
Eni t’o ti s’alaileso si dupe
Fun ‘se ogo ola re

4. Eni t’ebi npa le ri ayo ninu
Agbara nla re to ga
Awon to ti nwoju re fun anu
Won tun nyo n’nu ise re.

5. F’alafia re fun ijo re l’aye
K’ore-ofe re ma ga;
K’awon eni tire ko ma yo titi
Ninu ogo ise re. Amin.

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *