Oluwa Mi, Mo n Jade Lọ (Yoruba Hymns)

Oluwa Mi, Mo n Jade Lọ

OLUWA mi, mo n jade lọ,
Lati se isẹ ojọ mi,
Iwọ nikan l’emi o mọ,
L’ọrọ, l’ero, ati n’ise.

Isẹ t’o yan mi l’anu RẸ,
Jẹ ki n le se tayọtayọ;
Ki n roju Rẹ ni isẹ mi,
K’emi si le f’ifẹ Rẹ han.

Dabobo mi lọwọ ‘danwo,
K’o pa ọkan mi mọ kuro,
L’ọwọ aniyan aye yi,
Ati gbogbo ifẹkufẹ.

Iwọ t’oju Rẹ r’ọkan mi,
Ma wa lọw’ ọtun mi titi;
Ki n ma sisẹ lọ lasẹ Rẹ,
Ki n f’isẹ mi gbogbo fun Ọ.

Jẹ ki n r’ẹru Rẹ t’o fuyẹ,
Ki n ma sọra nigba gbogbo;
Ki n ma f’oju si nkan t’ọrun,
Ki n si mura d’ọjọ ogo.

Ohunkohun t’o fi fun mi,
Jẹ ki n le lo fun ogo Rẹ;
Ki n f’ayọ sure ije mi,
Ki n ba Ọ rin titi d’ọrun.

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *