Eyin Oba Ogo, On ni Olorun (Yoruba Hymns)

Eyin Oba Ogo, On ni Olorun

Eyin Oba ogo, On ni Olorun
Yin fun ‘se ‘yanu ti o ti fihan
O wa pelu awon ero mimo l’ona
O si je imole won l’osan l’oru.

E yin Angel ‘didan, lu duru wura
Ki gbogbo yin juba, t’e now oju re
Ni gbogbo ‘joba re, b’aye ti nyi lo

Ise re y’o ma yin
Ise re y’o ma yin
Fi ibukun fun Oluwa okan mi.

E yin fun ‘rapada ti gbogbo okan
E yin fun orisun imularada
Fun inu rere ati itoju re
Fun ‘daniloju pe O ngbo adura,

E yin fun idanwo bi okun ife,
T’o nso wa po moa won ohun orun
Fun ‘gbagbo ti n|”segun , ‘reti ti ki sa
Fun ile ogo t’O  ti pese fun wa.

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *