Oluwa Mbo Aye O Mi (Yoruba Hymns)

Oluwa Mbo Ayé O Mi

1. Oluwa mbo; ayé o mi,
Oke y’o sidi n’ipo won,
At’ irawo oju orun,
Y’o mu imole won kuro.

2. Oluwa mbo; bakan naa ko,
Bi o ti wa n’irele ri;
odo-aguntan ti a pa,
eni-iya ti o si ku.

3. Oluwa mbo; ni eru nla,
L’owo ina pelu ija,
L’or’ iye apa Kérúbù,
Mbo, Onidajo arayé.

4. Eyi ha ni eni ti n rin,
Bi ero l’opopo ayé?
Ti a se ‘nunibini i?
A! eni ti a pa l’eyi?

5. Ika: b’e wo ‘nu apata,
B’e wo ‘nu iho, lasan ni;
Sugbon igbagbo t’o segun
Y’o korin pe, Oluwa de.

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *