Oluwa, Emi Sa Ti Gb’ohun Re (Yoruba Hymns)

Oluwa, Emi Sa Ti Gb’ohun Re

1. Oluwa emi sa ti gb’ohun Re
O nso ife Re simi
Sugbon mo fe nde l’apa igbagbo
Ki nle tubo sun mo o

Fa mi mora, mora, Oluwa
Sib’agbelebu t’O ku
Fa mi mora, mora, mora Oluwa
Si b’eje Re t’o n’iye

2. Ya mi si mimo fun ise Tire
Nipa ore-ofe Re
Je ki nfi okan igbagbo w’oke
K’ife mi si je Tire

3. A ! ayo mimo ti wakati kan
Ti mo lo nib’ite Re
‘gba mo ngb’adura si O Olorun
Ti a soro bi ore.

4. Ijinle ife mbe ti nko le mo
Titi un o koja odo
Ayo giga ti emi ko le so
Tit un o fi de ‘simi. Amin.

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *