Bi Mo Ti Ri, Lai S’awawi

Bi Mo Ti Ri, Lai S’awawi

1. Bi mo ti ri, lai s’awawi
Sugbon nitori eje Re
B’o si ti pe mi pe ki nwa
Olugbala, mo de.

2. Bi mo ti ri, laiduro pe
Mo fe k ‘okan mi mo toto
S’odo Re to le we mi mo
Olugbala, mo de

3. Bi mo ti ri, b’o tile je
Ija l’ode, ija ninu
Eru l’ode, eru ninu
Olugbala, mo de

4. Bi mo ti ri, osi are
Mo si nwa imularada
Iwo le s’awotan mi
Olugbala, mo de.

5. Bi mo ti ri ‘wo o gba mi
‘wo o gba mi, t’owo t’ese
‘tori mo gba ‘leri Re gbo
Olugbala, mo de.

6. Bi mo ti ri ife Tire
L’o sete mi patapata
Mo di Tire, Tire nikan
Olugbala, mo de.

7. Bi mo ti ri, n’nu ‘fe nla ni
T’o fi titobi Re han mi
Nihin yi ati ni oke
Olugbala, mo de. Amin.

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *