Skip to content
Home » Yoruba Hymns » Okan Mi Nyo Ninu Oluwa (Yoruba Hymns)

Okan Mi Nyo Ninu Oluwa (Yoruba Hymns)

    Okan Mi Nyo Ninu Oluwa
    1. Okan mi nyo ninu Oluwa
    ‘Tori O je iye fun mi
    Ohun Re dun pupo lati gbo
    Adun ni lati r’oju Re

    [Egbe]
    Emi nyo ninu Re
    Emi nyo ninu Re
    Gba gbogbo lo fayo kun okan mi
    ‘Tori emi nyo n’nu Re.

    2. O ti pe t’O ti nwa mi kiri
    ‘Gbati mo rin jina s’agbo
    O gbe mi w asile l’apa Re
    Nibiti papa tutu wa

    3. Ire at’anu Re yi mi ka
    Or’ofe Re nsan bi odo
    Emi Re nto, o si nse ‘tunu
    O mba mi lo si ‘bikibi

    4. Emi y’o dabi Re ni ‘jo kan
    Un o s’eru wuwo mi kale
    Titi di ‘gbana un o s’oloto
    Ni sise oso f’ade Re. Amin.

    Other Yoruba Hymns Lyrics
    [display-posts category=”Yoruba Hymns” exclude_current=”true”]

    Leave a Reply

    Your email address will not be published. Required fields are marked *