Nigba Kan Ni Betlehemu (Yoruba Hymns)

Nigba Kan Ni Betlehemu

Nigba kan ni Betlehemu
Ile kekere kan wa
Nib’i’ya kan te mo’re si
Lori ibuje eran
Maria n’iya omo na
Jesu Kristi l’omo na

O t’orun wa s’ode aye
On l’Olorun Oluwa
O f’ile eran se ile
‘Buje eran fun ‘busun
Lodo awon otosi
Ni Jesu gbe li aye

Ni gbogbo igba ewe Re
O ngboran o si mb’ola
O feran Osi nteriba
Fun iya ti ntoju Re!
Oye ki gbogbo’ omode
K’o se olugboran be

‘Tori on je awose wa
A ma dagba bi awa
O kere ko le da nkan se
A ma sokun bi awa
O si le ba wa daro
O le ba wa yo pelu

A o foju wa ri nikehin
Ni agbara ife re
Nitori omo rere yi
Ni Oluwa wa l’orun
O nto awa omo re
S’ona ibiti On lo

Ki se ni ibuje eran
Nibiti malu njeun
L’awa o ri; sugbon lorun
Lowo otun ‘Olorun
‘Gba ‘won ‘mo Re b’irawo
Ba wa n’nu aso la

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *