Baba Mi Gbọ Temi (Yoruba Hymns)

Baba Mi Gbọ Temi

Baba mi gbọ temi!
‘Wọ ni Alabo mi,
Ma sunmọ mi titi;
Oninure julọ!

Jesu Oluwa mi,
Iye at’ogo mi,
K’igba naa yara de,
Ti n ó de ọdọ Rẹ.

Olutunu julọ,
‘Wọ ti n gbe inu mi,
‘Wọ to mọ aini mi,
Fa mi, k’o si gba mi.

Mimọ, mimọ, mimọ,
Ma fi mi silẹ lai,
Se mi n’ibugbe Rẹ,
Tirẹ nikan lailai.

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *