Ma Gesin Lo L’ola Nla Re (Yoruba Hymns)

Ma Gesin Lo L’ola Nla Re

Ma gesin lo l’ola nla Re;
Gbo gbogb’ayé, n ke “Hosanna”
Olugbala, ma lo pele,
Lori im’ope at’aso.

Ma gesin lo l’ola nla Re;
Ma f’irele gesin lo ku;
Kristi, segun Re bere na;
Lori ese ati iku.

Ma gesin lo l’ola nla Re;
Ogun Angeli lat’orun;
N f’iyanu pelu ikanu,
Wo ebo to sunmole yi.

Ma gesin lo l’olanla Re;
Ija ikehin na de tan;
Baba, lor’ite Re l’orun,
N reti ayanfe omo Re.

Ma gesin lo l’olanla Re;
Ma f’irele gesin lo ku;
F’ara da irora f’eda;
Lehin na, n de k’O ma joba

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *