Home >> Yoruba Hymns

Ijinle ni ife Jesu (Yoruba Hymns)

1. Ijinle ni ife Jesu
O ga pupo, ofe ni
Bi igbi omi okun nla
Beni ife Re si mi
L’otun l’osi, nihin, lohun
Ni mo nri ife Re yi
O nto mi lo l’ona iye
Titi ngo de ile mi

2. Ijinle ni ife Jesu
Korin iyin Re kiri
Bi ife Re ti tobi to
Ife ti ki yipada
O nse ‘toju awon Tire
T’o ti fi eje Re ra
O mbebe fun won l’ori ‘te
O npa won mo lat’oke

3. Ijinle ni ife Jesu
Kos’ eyit’a le fi we
Orisun ibukun lo je
Ibi ‘simi okan mi
Ijinle ni ife Jesu
Ti nfa okan mi soke
Ti ngbe orun ka ‘waju mi
Ti ngbe mi s’inu ogo

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *