A F’ope f’Olorun (Yoruba Hymns)

A F’ope f’Olorun

1. A f’ope f’Olorun
L’okan ati l’ohun wa
Eni s’ohun ‘yanu
N’nu eni t’araye nyo
‘gbat’a wa l’om’owo
On na l’o ntoju wa
O si nf’ebun ife
Se ‘toju wa sibe.

2. Oba Onib’ore
Ma fi w asile laelae
Ayo ti ko l’opin
On ‘bukun y’o je ti wa
Pa wa mo n’nu ore
To wa, gb’a ba damu
Yo wa ninu ibi
L’aye ati l’orun

3. K’a f’iyin on ope
F’Olorun, Baba, Omo
Ati Emi mimo
Ti O ga julo lorun
Olorun kan laelae
T’aye at’orun mbo
Be l’o wa d’isiyi
Beni y’o wa laelae.

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *