Skip to content
Home » Onisegun Nla Wa Nihin (Yoruba Hymns)

Onisegun Nla Wa Nihin (Yoruba Hymns)

  Onisegun Nla Wa Nihin

  1. Onisegun nla wa nihin
  Jesu abanidaro
  Oro Re mu ni l’ara da
  Agbo ohu ti Jesu

  Egbe
  Iro didun lorin Seraf
  Oruko didun n’nu enia
  Orin t’o dun julo ni
  Jesu, Jesu, Jesu

  2. A fi gbogb’ ese re ji o
  A gbo ohun ti Jesu
  Rin lo s’orun l’alafia
  Si ba Jesu de ade

  3. Gbogb’ ogo fun Krist’ t’o jinde
  Mo gbagbo nisisiyi
  Mo f’oruko Olugbala
  Mo fe oruko Jesu

  4. Oruko Re l’eru mi lo
  Ko si oruko miran
  B’ okan mi ti nfe lati gbo
  Oruko Re ‘yebiye

  5. Arakunrin e ba mi yin
  A yin oruko Jesu
  Arabirin, gb’ohun s’oke
  A yin oruko Jesu

  6. Omode at’agbalagba
  T’o fe oruko Jesu
  Le gba ‘pe ‘fe nisisiyi
  Lati sise fun Jesu

  Other Yoruba Hymns Lyrics
  [display-posts category=”Yoruba Hymns” exclude_current=”true”]

  0 thoughts on “Onisegun Nla Wa Nihin (Yoruba Hymns)”

  Leave a Reply

  Your email address will not be published. Required fields are marked *