Ire Ta Su Ni Eden (Yoruba Hymns)

Ire Ta Su Ni Eden

1.Ire ta su ni Eden
N’igbeyawo kini
Ibukun t’a bunkun won
O wa sibesibe.

2.Sibe titi di oni
Ni igbeyawo Kristiani
Ibukun t’a bukun won
Lati sure fun won

3.Ire ki nwon le ma bi
Ki nwon k’osi ma re
Ki nwon n’idapo mimo
T’enikan k’y’o le tu

4.Bawa pe, Baba si fa
Obirin yi f’oko
Bi o ti fa Efa fun
Adam l’ojo kini

5.Ba w ape Emmanuel
Si so owo won po
B’eda meji ti papo
L’ara ijinle Re

6.Ba wa pe Emi Mimo
F’ibukun Re fun won
Si se won ni ase pe
Gege b’O ti ma nse

7.Fi won sabe abo Re
K’ibi, kan ma ba won
Gba nwon npara ile re
Ma toju okan won

8.Pelu won loj’aiye won
At’oko ataya
Titi nwon o d’odo Re
N’ille ayo lorun.

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *