Site icon GMLyrics

Gbata B’Oluwa Rin (Yoruba Hymns)

Gbata B'Oluwa Rin (Yoruba Hymns)

Gbata B’Oluwa Rin

1. ‘Gbat a b’Oluwa rin
N’nu mole oro re
Ona wa yio to mole to
‘Gbata a ba nse ‘fe Re
On yio ma ba wa gbe
Ati awon t’o gbeke won le

Egbe
Sa gbeke le, Ona miran ko si
Lati l’ayo n’nu Jesu
Ju pe k’a gbekele

2. Ko s’ohun t’o le de
L’oke tabi ni’le
T’o le ko agbara Re l’oju
Iyemeji, eru, ibanuje, ekun
Ko le duro bi a gbekele

3. Ko si wahala mo
Tabi ibanuje
O ti san gbogbo gbese’ wonyi
Ko si arokan mo, Tabi ifa juro
Sugbon bukun, b’a ba gbeke le

4. Ako le f’enu so
Bi ‘fe Re ti po to
Titi ao fi f’ara wa rubo
Anu ti o nfihan
At’ayo t’o nfun ni
Je ti awon ti o gbeke le

5. Ni ‘dapo pelu Re
Ao joko lese Re
Tabi ki a ma rin pelu Re
Awa yo gbo ti Re
A o jise  to ran wa
Ma beru sa gbekele nikan

Other Yoruba Hymns Lyrics
[display-posts category=”Yoruba Hymns” exclude_current=”true”]

Exit mobile version