Site icon GMLyrics

Fi iyin fun! Jesu Olurapada wa (Yoruba Hymn)

Fi iyin fun! Jesu Olurapada wa (Yoruba Hymn)

1. Fi iyin fun! Jesu Olurapada wa
Ki aiye k’okiki ife Re nla
Fi iyin fun! Enyin Angeli ologo
F’ola at’ogo fun oruko Re
B’Olusoagutan,Jesu y’o to omo Re
Apa Re lo ngbe won le lojojo
Enyin enia mimo ti ngb’oko Sion
Fi iyin fun, Pelu orin ayo

2. Fi iyin fun! Jesu Olurapada wa
Fun wa O t’eje Re sile, O ku
On ni apata ati’reti ‘gbala wa
Yin Jesu ti a kan m’agbelebu
Olugbala t’O f’ara da irora nla
Ti a fi ade egun de lori
Eniti a pa nitori awa eda
Oba ogo njoba titi lailai

3. Fi iyin fun! Jesu Olurapada wa
Ki ariwo iyin gba orun kan
Jesu Oluwa njoba lai ati lailai
Se l’Oba gbogbo‘enyin alagbara
A segun iku; Fi ayo rohin na ka
Isegun re ha da, isa-oku?
Jesu ye! Ko tun si wahala fun wa mo
‘Tori O l’agbara lati gbala

Exit mobile version