Yin Oluwa, o to, o ye (Yoruba Hymns)

1. Yin Oluwa, o to, o ye
K’a fokan at’ohun wa yin
Ise re t’a nri lo mu wa
K’a f’ayo korin iyin Re

2. Enit’o d’awon irawo
T’o si fun won ni oruko
Awamaridi l’ogbon Re
Imo Re ga ju ero wa

3. Korin, si gbe Oluwa ga,
Enit’o da awosanma
Eniti nrojo ibukun
Ti nmu irugbin wa dagba

4. On l’o da awon oke nla
O nwo itanna li aso
O mbo gbogbo’eranko igbe
Okan ko k’ebi ninu won

5. Agbara Re l’enia nlo
Agbara Re l’eranko nle
Tire ni ipa at’ogbon
Laisi Re kini eda je?

6. Inu Re ndun si omo Re
Awon t’o f’eje ra pada
O nwo aworan Re n’nu won
O ntoju won O npa won mo

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *