Skip to content
Home » Yoruba Hymns » Yika Or’ite Olorun (Yoruba Hymns)

Yika Or’ite Olorun (Yoruba Hymns)

    Yika Or’ite Olorun

    1. Yika or’ite Olorun,
    Yika or’ite Olorun,
    Egberun ewe wa;
    Ewe t’a dari ese ji,
    Awon egbe mimo;

    Egbe
    N korin ogo, ogo, ogo.
    N korin ogo, ogo, ogo

    2. Wo! olukuluku won wo,
    Aso ala mimo;
    Ninu imole ailopin,
    At’ayo ti ki sa,
    N korin ogo, ogo, ogo.

    3. Ki l’o mu won de ayé na,
    Orun t’o se mimo,
    Nib’ alafia at’ayo,
    Bi won ti se de ‘be?
    N korin ogo, ogo, ogo.

    4. Nitori Jesu ta ‘je Re,
    Lati k’ese won lo;
    A ri won ninu eje na,
    Won di mimo laulau;
    N korin ogo, ogo, ogo.

    5. L’ayé, won wa Olugbala,
    Won fe oruko Re;
    Nisinsin yi won r’oju Re,
    Won wa niwaju Re;
    N korin ogo, ogo, ogo.

    6. Orisun na ha n san loni?
    Jesu, mu wa de ‘be;
    K’a le ri awon mimo na,
    K’a si ba won yin O,
    N korin ogo, ogo, ogo.

    Other Yoruba Hymns Lyrics
    [display-posts category=”Yoruba Hymns” exclude_current=”true”]

    Leave a Reply

    Your email address will not be published. Required fields are marked *