Wakati Adura Didun
Wakati adura didun!
T’o gbe mi lo kuro l’ayé,
Lo ‘waju ite Baba mi,
Ki n so gbogbo edun mi fun;
Nigba ‘banuje at’aro,
Adua l’abo fun okan mi:
Emi si bo lowo Esu,
‘Gbati mo ba gb’adua didun
Emi si bo lowo Esu,
‘Gbati mo ba gb’adua didun
Wakati adura didun!
Iye re y’o gbe ebe mi,
Lo sod’ eni t’o se ‘leri,
Lati bukun okan adua:
B’O ti ko mi, ki n woju Re,
Ki n gbekele, ki n si gb’ gbo:
N ó ko gbogb’ aniyan mi le,
Ni akoko adua didun,
N ó ko gbogb’ aniyan mi le,
Ni akoko adua didun.
Wakati adura didun!
Je ki n ma r’itunu re gba,
Titi n ó fi d’oke Pisga,
Ti n ó r’ile mi l’okere,
N ó bo ago ara sile,
N ó gba ere ainipekun:
N ó korin bi mo ti n fo lo,
O digbose! Adua didun,
N ó korin bi mo ti n fo lo,
O digbose! adua didun.
Other Yoruba Hymns Lyrics
[display-posts category=”Yoruba Hymns” exclude_current=”true”]
Ayanniyi Arinola says
This song has ever been my consolation and it also build my heavenly home assurance. Thanks for the lyrics.