Skip to content
Home » Tayotayo l’awa (Yoruba Hymns)

Tayotayo l’awa (Yoruba Hymns)

  1. Tayotayo l’awa
  O ma juba Re
  Pelu okan ope
  L’awa o yin O
  Iho orin ayo wa y’o goke lo
  Sodo Olorun
  Olubukun julo

  2. Ola t’o ye O
  L’awa o fifun O
  Eniti aiye ati
  Orun njuba
  Eda t’o wa n’ile ati nin’okun
  Gbogbo won nwole
  Niwaju Oba won

  3. Nipa Emi Re l’a
  Fi so wa d’otun
  Irapada l’o so
  Wa d’Om’Olorun
  Titi l’ao ma dupe
  Ore t’o se wa
  Ko wa. Baba, bi a
  Ti nyin O l’ogo

  4. Pelu awon Angel’
  Awa njuba Re
  Ki Halleluya wa
  Dapo mo ti won
  Beni! Ogo ye O
  l’aiye at’orun
  ‘Wo l’o raw a pada
  T’a di asegun

  Other Yoruba Hymns Lyrics
  [display-posts category=”Yoruba Hymns” exclude_current=”true”]

  Leave a Reply

  Your email address will not be published. Required fields are marked *