Skip to content
Home » Sola Allyson » Sola Allyson – Ope Lyrics

Sola Allyson – Ope Lyrics

  Lyrics for Ope By Sola Allyson

  Nipa ipa ko, kii s’agbara l’oro se ri b’o se ri
  B’o ti wu ko ri Oluwa s’olododo f’awon to gba A gbo
  Oye aye o ye ni to sugbon o da wa loju Alaanu l’Olorun wa

  A gbe ni leke, Oluke ni, Oluyan ni sola
  Aseyiowu O se o Baba t’o fi wa dara iyanu

  (Iba Iba Iba)
  Iba o
  Iba f’Olorun Eledumare to l’ogo oooo (iba)
  Iba Iba Iba naa ni o (Iba o)
  Iba Iba Iba o

  A juba, a juba, f’Olorun to ni gbogbo ogo, Oun ni (Iba o)
  Iba l’awa f’aye wa ju oo (Iba o)
  Iba, a juba Re, Iwo nikan lo ni gbogbo ijuba a wa (Iba o)
  Iba Iba Iba

  Ope ni fun o Edumare, Oba to laye
  Ada Ehini magbagbe Oba Oke to segun fun wa
  Bi ko ba se ‘Wo too seyi fun wa ki la a ba wi o
  Ope wa ree o, Oba to to gb’oju le

  A mo riri oore t’Oo se fun wa o, Oba to to gb’oju le
  Okeere ni mo gbe wa o, mo gburo ise Oluwa
  Ta lo dabi Re ninu aanu, adani ma gbagbe eni

  Bi’da keji ba sele, Oo sa ma j’Olohun lo ni
  O ka wa m’awon t’Oo pe, t’Oo yan
  Oba to to gb’oju le
  O ka wa m’awon t’Oo s’aanu fun
  A o le dupe tan lai lai lai lai

  You are the Lord above all the earth
  Kabi o o si o
  You are the Lord above all the earth
  Kabi o o si o

  Oju mi ti ri, eti mi ti gbo
  Iyanu Re yi aye ka
  Mo gbo ninu eri awon eniyan mimo
  Mo ri ninu itan, emi gangan ni itan

  Gbogbo ise Re daa da’a da’a da’a ni
  Aburu kankan o t’odo Re wa
  Ohun gbogbo lo le yi pada
  Sugbon rara t’ododo Re ko

  Kabiyesi oooo, mo se ba Re
  Oba to ju gbogbo oba lo
  Kabiyesi ooo
  Kabiyesi o mo se ‘ba Re
  Oba to ju gbogbo oba lo

  Afuye gege ti o see gbe
  Jigbinni jigbinni bi ate ileke
  Kabiyesi o mo se ‘ba Re
  Oba to ju gbogbo oba lo

  Afuye gege ma ma see gbe
  Jigbinni jigbinni bi ate ileke
  Kabiyesi o mo se ‘ba Re
  Oba to ju gbogbo oba lo

  Mo se ‘ba Re o, mo se ‘ba Re
  Mo f’ori bale mo gb’owo soke
  Mo se’ba Re o, mo se ‘ba Re
  Ni ‘rele okan mi ni mo wari
  Kabiyesi o mo se ‘ba Re
  Oba to ju gbogbo oba lo

  Kabiyesi o
  Kabiyesi o mo se ‘ba Re
  Oba to ju gbogbo oba lo

  Aigbagbo bila temi l’Oluwa
  Oun yoo si dide fun igbala mi
  Ki n sa ma gb’adura
  Ki n sa ma gb’adura
  Oun o se ‘ranwo
  ‘Gba Krist’ wa l’odo mi ifoya ko si

  B’ona mi ba su, Oun lo sa n to mi
  Ki n sa gboran sa Oun o si pese
  B’ona mi ba su o, Oun lo sa n to mi
  Ki n sa gboran sa Oun o si pese
  Bi ‘ranlowo eda
  Bi ‘ranlowo eda gbogbo saki
  Oro t’enu Re n so yoo bori dandan

  Hallelujah
  Hosanna
  Hallelujah
  Hossanah
  Hallelujah l’awon orun nke
  Hossanah
  Awa aye naa nke tiwa, hallelujah
  Hossanah

  Hallelujah
  Hossanah (hossanah hossanah l’awa nko)
  Hallelujah (Hossanah)
  Gbogbo iseda n f’ori bale f’ooko Re, Hallelujah
  Hossanah
  Hallelujah
  Hossanah

  Our Father
  We bless You
  Olutoju wa, we bless You
  We bless You
  Eni to l’emi to fun wa mi, we bless You
  We bless You
  Eni t’O fi ‘ranwo fun wa, we bless You
  We bless You

  Eeeh Oluwa, Eeeeh ehhh Oluwa
  Eeeeh Oluwa o b’ona ba su
  Oluwa f’ona han wa, Oluwa o

  Eeeh Oluwa, Eeeeh ehhh Oluwa o
  Eeeeh Oluwa o b’ona ba su
  Oluwa f’ona han wa, Oluwa o

  Ife t’O fi han ko je ki n ro pe
  Yio fi mi sile ninu wahala
  Oun to mu mi de bi s’olododo lati sun mi siwaju
  Ko ni fi mi sile bo ti le wu ko ri o

  Iranwo ti mo si
  Iranwo ti mo si n ri lojojumo
  O ki mi l’aya pe emi yoo laaja

  Olorun agbaye
  You are mighty
  Olorun to wa ninu awon orun to ju awon orun lo (You are mighty)
  Ori obiri aye lo n gbe imole lo fi saso bora o (You are mighty)

  O f’orun se ‘le, O f’aye s’apoti itise maa s’ola Re lo (You are mighty)
  You are mighty, You are wonderful, You are awesome, oruko Re niyen (You are mighty)

  Olorun agbaye (You are mighty)
  Sebi ‘Wo lo f’oju orun saso bora
  Olorun agbaye o, You are mighty o
  Olorun agbaye o You are mighty

  Sebi ‘Wo lo f’oju orun saso bora
  Olorun agbaye o, You are mighty o

  Oruko Oluwa ile iso agbara ni
  Olododo sa wo’nu re, o ri iye
  Emi naa, mo sa wo’nu re, mo ri iye
  Oruko Re ti niyin to (Oluwa Oluwa)
  Oluwa, Oluwa wa, oruko Re ti niyin to

  Oluwa Oluwa Oluwa
  Oluwa, Oluwa wa, oruko Re ti niyin to

  Alagbara l’Olorun wa
  Agbara agbara agbara yi po o, agbara
  Oba to ba riru omi okun wi, agbara Re po
  Agbara agbara agbara yi po o, agbara

  A wo ‘gba aarun, ma gb’eje l’ooko Re
  Agbara agbara agbara yi po o, agbara

  Oba to f’aanu tan ‘mole s’ona awon to gb’oju s’oke si
  Agbara agbara agbara yi po o, agbara
  O f’agbara gba ni lowo alagbara gbangba ti n f’owo agbara je ni niya
  Agbara agbara agbara yi po o, agbara

  Gbogbo iseda n wariri ni’waju agbara Re
  Agbara agbara agbara yi po o, agbara

  Iba o
  Iba f’Olorun Eledumare to ni gbogbo ogo (Iba)
  Iba Iba a (Iba)

  A juba, a juba, gbogbo ijuba wa tire ni (Iba)
  Olorun to ni gbogbo ogo, iba f’ooko Re (Iba)
  Gbogbo iseda n f’ori bale ni’waju Re (Iba)
  Iba Iba Iba a

  Ise Re po, o po, o po, o po gaan ni (Iba)

  Awon ise iyanu t’Oo ti se, ta lo le ka won tan? (Iba)
  Ta lo le so ewa Re to po, to po gaan ni? (Iba)
  Iba Iba Iba Iba (Iba)

  Gbogbo eemi mi, gbogbo wiwa mi, tire lo je, mo juba (Iba)
  Titi aye ni ma ma se’ba Re lojojumo (Iba)
  Maa sin O d’opin igba mi, Iba Iba (Iba)
  Iba aaa

  Other Sola Allyson Lyrics
  [display-posts category=”Sola Allyson” exclude_current=”true”]

  Tags:

  Leave a Reply

  Your email address will not be published. Required fields are marked *