Home >> Sola Allyson

Sola Allyson – Mo Ju Ba Lyrics

Lyrics for Mo Ju Ba By Sola Allyson

Mo juba Oba, Mo juba Oba
Iba Eledumare, to ni gbogbo ogo
Atererekariaye Olorun Awon Omo Ogun
Mo juba Oba

Mo juba Oba, Mo juba Oba
Iba Eledumare, to ni gbogbo ogo
Atererekariaye Olorun Awon Omo Ogun
Mo Ju Ba

Iba Eledumare, Oba to ni gbogbo aye
Eni nla ti mbe lori ite titi lai lai lai
Emi mi b’ola fun O o lati ogbun iseda mi
Mo yi ka otun, mo yi t’osi mo ba ruburubu
F’Eni naa Alaponlejulo, Eni Ayeraye

Iwo lo ti mbe, Iwo loo si ma be,
Leyin Re, ko si mo, Oba titi lai
Mo sin O, Mo sin O, Mo sin O
Lat’ogbun emi mi
Eni naa, Oba naa, Oluwosan, Alaanu
Gbogbo iseda ati emi, a n b’ola fun O

Mo juba Oba, Mo juba Oba
Iba Eledumare, to ni gbogbo ogo
Atererekariaye Olorun Awon Omo Ogun
Mo juba Oba

Iwo ni Oba ti o le pa’poda lailai
Oba to ti wa ti o si ma be tititi
Aye mi yio ma fi ibukun fun oruko Re
Ileke ola, Ipile oye, opin gbogbo ola
Gbogbo ise Re ni o ma yin O, a n pe O lOba

Iwo ni Alaanu to f’ebun se mi loso
O tun fi ogo de ebun to fun mi lade
Odo Re naa ni gbogbo ogo naa n pada si Oluwa
Eni naa, Oba naa, Oluwosan, Alaanu
Gbogbo iseda ati emi, a n b’ola fun O

Gbogbo ise Re ati emi o
A n b’ola fun O
Awon ohun taa ri at’awon ta o ri, won n b’ola fun O
A n b’ola fun O
Loke orun lohun, lagbedemeji ile t’a n te, ogo ni f’ooko Re
A n b’ola fun O
Iwo ni O ni ike to po, Olola to po, Alaanu to po
A n b’ola fun O

Ko si ede naa ni gbogbo aye ti iro ogo Re kii buyo Oluwa
A n b’ola fun O
Hiho okun n bu ola fun O, Osa naa n b’ola fun O, gbogbo ise.
A n b’ola fun O
Gbogbo ede, gbogbo ijoba, lo n wariri fun Oruko Re
A n b’ola fun O
Gbogbo ise Re ati emi
A n b’ola fun O

Other Sola Allyson Lyrics

Tags:

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *