Pelu duru wura, gbogbo won duro (Yoruba Hymn)

1. Pelu duru wura, gbogbo won duro
Nwon nko orin titun niwaju Oluwa

Egbe
Si Eniti O fe wa t’o w’ese wa nu
On li ogo, ola, ye fun lailai. Amin.

2. Elese ni nwon ti je nigbakan ri
Nisisiyi a ti wo won l’aso funfun

Egbe

3. O s’olote di alufa at’oba
O gba wa, Osi ko wa l’orin titun yi

Egbe

4. Awa ti ko ni ireti kan l’aiye
Ibasepe ko gba wa, nibo l’a o lo?

Egbe

5. O ye k’a gbe ohun iyin wa soke
K’awon t’o yi wa ka le korin didun yi.

Egbe

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *