Olorun Awamaridi (Yoruba Hymns)

1. Olorun awamaridi
Tal’oye k’a f’okan wa fun
Tal’o ye ki a tun feran
Jesu Olufe okan wa
Tal’oye k’a fi okan wa
Ati agbara wa feran

2. Ogo oju Oluwa ndan
Ogo ti eda ko le wo
Awon Angeli mb’oju won
Sibe oore Re bi odo
Nsan s’ori ise Re gbogbo
Aanu re si yi aiye ka

3. Iwo Orisun ibukun
K’ilohun t’Iwo se aini
Kil’a le fit e O lorun
Sibesibe, Iwo mbere,
Pe kin le f’okan mi fun O.
Eyi nikan n’Iwo mbere

4. Iwo t’ite Re mbe l’oke
Ti ‘joba Re ko nipekun
O npase lori gbogbo won
Sibesibe, O to mi wa
Lati ma se Amona mi
Titi ngo fi ba O joba

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *