Olorun aiye at’orun (Yoruba Hymn)

1. Olorun aiye at’orun
To da orun at’irawo
Iye Re ni gbogbo wa ngba
‘Wo lo nru ife wa soke

2. Iwo l’orun ododo wa
Lati s’amona wa l’osan
Iwo n’imole wa l’oru
Irawo ti ntan yi wa ka

3. B’iwo ba kuro lodo wa
Okunkun y’o bow a mole
Anu Re nikan l’a romo
Lati segun gbogbo ese

4. Iwo njoba l’oke, n’ile
Otito ni imole Re
Ogo Re l’awa nsaferi
A ko fe ogo t’ara wa

5. F’otito Oro Re han wa
Lati so wa d’ominira
Mu k’okan wa gbona loni
K’a f’ara wa rubo fun O

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *