Okan mi, yin Oba orun (Yoruba Hymn)

1. Okan mi, yin Oba orun
Mu ore wa s’odo Re
‘Wo t’a wosan t’a dariji
Tal’a ba ha yin bi Re
Yin Oluwa! Yin Oluwa!
Yin Oba ainipekun

2. Yin fun anu t’O ti fihan
F’awon baba n’nu ‘ponju
Yin I, okan na ni titi
O lora lati binu
Yin Oluwa! Yin Oluwa!
Ologo n’nu otito

3. Bi baba ni O ntoju wa
O si mo ailera wa
Jeje l’O ngbe wa l’apa Re
O ngba wa lowo ota
Yin Oluwa
Anu Re yi aiye ka

4. A ngba b’itanna eweko
T’afefe nfe, t’o si nro
‘Gbati a nwa ti a si nku
Olorun wa bakanna
Yin Oluwa
Oba alainipekun

5. Angeli, e jumo bawa bo
Enyin nri lojukoju
Orun, osupa e wole
Ati gbogbo agbaiye
E ba wa yin
Olorun Olotito

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *