Ogo Ni F’Oluwa T’o Se Ohun Nla (Yoruba Hymns)

Ogo Ni F’Oluwa T’o Se Ohun Nla

Ogo ni f’Oluwa t’o se ohun nla
Ife lo mu k’O fun wa ni omo re
Eni t’o f’ emi re lele f’ese wa
To si Ilekun iye sile fun wa.

Yin Oluwa, Yin Oluwa
Fiyin fun Oluwa
Yin Oluwa, Yin Oluwa
E yo niwaju re
K’a to Baba wa lo l’oruko Jesu
Jek’a jo f’ogo fun onise ‘yanu

Irapada kikun ti eje re ra
F’enikeni t’o gba ileri re gbo
Enit’o buruju b’oba le gbagbo
Lojukanna yo ri idariji gba

O s’ohun nla fun wa, o da wa l’ola
Ayo wa di kikun ninu Omo re,
Ogo ati ewa irapada yi,
Y’o ya wa lenu ‘gbata ba ri Jesu.

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *