O Fun Mi L’edidi
1. O fun mi l’edidi,
‘Gbese nla ti mo je,
B’o ti fun mi, o si rerin,
Pe, “Mase gbagbe mi!”
2. O fun mi l’edidi,
o san igbese na;
B’o ti fun mi, o si rerin,
Wi pé, “Ma ranti mi!”
3. N ó p’edidi na mo,
B’igbese tile tan;
o n so ife eni t’o san,
Igbese naa fun mi.
4. Mo wo, mo si rerin
Mo tun wo, mo sokun;
eri ife Re si mi ni,
N ó toju re titi.
5. Ki tun s’edidi mo,
Sugbon iranti ni!
Pe gbogbo igbese mi ni,
Emmanueli san.
Other Yoruba Hymns Lyrics
[display-posts category=”Yoruba Hymns” exclude_current=”true”]
Leave a Reply