1. Niwaju ite anu
Awa wole fun o
Awa nyin O, Oluwa
O dun lati mo O
2. Awa njuba re Jesu
Enit’ a pa fun wa
Iwo t’O njoba l’oke
T’O si tun npada bo
3. Awa njuba Re, Jesu
Fun irapada wa
Iwo fe wa l’afetan
Awa y’o ma yin O
4. Awa njuba Re Jesu
Ope la lo ye O
Titi l’a o ma yin O
Ao si se O l’ Oba