Mo Fe Ki Ndabi Jesu
1. Mo fe ki ndabi Jesu
Ninu iwa pele
Ko s’enu t’o gb’oro ‘binu
L’enu Re lekan ri
2. Mo fe ki ndabi Jesu
L’adura ‘gba gbogbo
Lori Oke ni on nikan
Lo pade Baba Re
3. Mo fe ki ndabi Jesu
Emi ko ri ka pe
Bi nwon ti korira Re to
O’ s’enikan ni’bi
4. Mo fe ki ndabi Jesu
Ninu ise rere
K’a le winipa t’emi pe
‘O se won to le se”
5. Mo fe ki ndabi Jesu
T’o f’iyonu wipe
“Je k’omode wa sodo mi”
Mo fe je ipe Re
6. Sugbon nko dabi Jesu
O si han gbangba be;
Jesu fun mi l’ore-ofe,
Se mi, ki ndabi Re
Other Yoruba Hymns Lyrics
[display-posts category=”Yoruba Hymns” exclude_current=”true”]
Leave a Reply