Ma Koja Mi, Olugbala (Yoruba Hymns)

Ma Koja Mi, Olugbala

1. Ma koja mi, Olugbala,
Gbo adura mi,
‘Gba t’Iwo ba n p’elomiran,
Mase koja mi!

Egbe
Jesu! Jesu! Gbo adura mi!
Gba t’Iwo ba n p’elomiran,
Mase koja mi.

2. N’ite anu je k’emi ri,
Itura didun;
Teduntedun ni mo wole,
Jo ran mi lowo.

3. N’igbekele itoye Re,
L’em’ o w’oju Re;
Wo ‘banuje okan mi san,
F’ife Re gba mi.

4. Jesu! Jesu! Gbo adura mi!
Gba t’Iwo ba n p’elomiran,
Mase koja mi.

5. ‘Wo orisun itunu mi,
Ju ‘ye fun mi lo;
Tani mo ni l’ayé l’orun
Bikose Iwo?

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *