K’a To Sun Olugbala Wa
1. K’a to sun Olugbala wa
Fun wa n’ ibukun ale
A jewo ese wa fun O
Iwo l’o le gba wa la
2. B’ ile tile ti sududu
Okun ko le se wa mo
Iwo eniti ki sare
Nso awon enia Re
3. B’ iparun tile yi wa ka
Ti ofa nfo wa koja
Awon Angeli yi wa ka
Awa o wa l’ ailewu
4. Sugbon b’ iku ba ji wa pa
Ti ‘busun wa d’ iboji
Je k’ ile mo wa sodo Re
L’ ayo at’ Alafia
5. N’ irele awa f’ara wa
Sabe abo Re Baba
Jesu ‘Wo t’o sun bi awa
Se orun wa bi Tire
6. Emi Mimo rado bo wa
Tan ‘mole s’ okunkun wa
Tit’ awa o fi ri ojo
Imole aiyeraiye
Other Yoruba Hymns Lyrics
- Jerry Hogan – More Than A Conqueror Lyrics
- Prince AKA – Testify Lyrics
- Olorun Awamaridi (Yoruba Hymns)
- E sin Oluwa ninu ewa iwa mimo (Yoruba Hymns)
- Jek’a jumo korin iyin (Yoruba Hymns)
- Gbo orin idasile (Yoruba Hymns)
- Ijinle ni ife Jesu (Yoruba Hymns)
- Tayotayo l’awa (Yoruba Hymns)
- Igbala! Iro ayo nla (Yoruba Hymns)
- Iwo Olurapada wa (Yoruba Hymns)