Jesu Ye Titi Aye (Yoruba Hymns)

Jesu Ye Titi Aye
1. Jesu ye: titi aye,
Eru iku ko ba mi mo;
Jesu ye: lat’ oni lo
Isa oku ko nipa mo
Alleluya!

2. Jesu ye: Nitorina
Iku je ona si iye;
Eyi y’oje ‘tunu wa,
‘Gbat’ akoko iku ba de
Alleluya!

3. Jesu ye: fun wa l’O ku
Nje tire ni a o maa se;
A o f’okan funfun sin I,
A o f’ogo f’Olugbala
Alleluya!

4. Jesu ye: eyi daju
Iku at’ ipa okunkun
Ki y’ o le ya ‘ni kuro
Ninu ife nla ti Jesu.
Alleluya!

5. Jesu ye: gbogbo ‘joba
Lorun li aye di Tire
E je ki a maa tele E
Ki a le joba pelu Re.
Alleluya! Amin.

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *