Irapada Itan Iyanu
1. Irapada ! itan iyanu
Ihin ayo fun gbogbo wa
Jesu ti ra ‘dariji fun wa
O san ‘gbese na lor’igi
[Egbe]
A ! elese gba ihin na gbo
Jo gba ihin oto na gbo
Gbeke re le Olugbala re
T’O mu igbala fun o wa
2. O mu wa t’inu ‘ku bo si ‘ye
O si so wa d’om’Olorun
Orisun kan si fun elese
We nin’eje na ko si mo
3. Ese ki y’o le joba wa mo
B’o ti wu ko dan waw o to
Nitori Kristi fi ‘rapada
Pa ‘gbara ese run fun wa
4. Gba anu t’Olorun fi lo o
Sa wa s’odo Jesu loni
‘Tori y’o gb’enit’o ba t’o wa
Ki yi o si da pada lae. Amin.
Other Yoruba Hymns Lyrics
[display-posts category=”Yoruba Hymns” exclude_current=”true”]
Leave a Reply