Gbogbo Eyin Ti Ngbe Aye
1 Gbogbo eyin ti ngbe aye
E f ayo korin s’Oluwa;
F’iberu sin, e yin l’ogo
E wa s’odo Re, k’e si yo.
2 Oluwa, On ni Qlorun,
Laisi ’ranwo wa O da wa;
Agbo Re ni wa, O mbo wa;
O si fi wa s’agutan Re.
3 Nje, f’iyin wo ile Re wa
F’ayo sunmo agbala Re;
Yin, k’e bukun oruko Re,
’Tori o ye be lati se.
4 Ese! rere l’Olorun wa,
Anu Re o wa titi lae,
Oto Re ko fi ’gbakan ye,
O duro lat’ irandiran.
Amin.
Other Yoruba Hymns Lyrics
[display-posts category=”Yoruba Hymns” exclude_current=”true”]
Leave a Reply