Home >> Yoruba Hymns

Gbo orin idasile (Yoruba Hymns)

1. Gbo orin idasile
Ti ndun bi ohun ara
Bi iro omi okun
‘Gbati igbi re ba nru
Halleluya! Olorun
Olodumare njoba
Halleluya! k’orin yi
Dun yi gbogbo aiye ka

2. Halleluyah! Gbo iro
Lati aiye de orun
Ti nji gbogbo enia
Loke ati n’isale
Oluwa gba isegun
O ti teri ota ba
Gbogbo ijoba aiye
Di ijoba Omo Re

3. Y’o joba yi aiye ka
Pelu agbara Re nla
Y’o joba ‘gbati orun
At’aiye ba koja lo
‘Gbana ni opin y’o de
Ao segun gbogbo ota
Halleluyah! Olorun
Pelu Krist’ l’ohun gbogbo

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *