Emi ‘ba n’egberun ahon (Yoruba Hymn)

1. Emi ‘ba n’egberun ahon
Fun ‘yin Olugbala
Ogo Olorun Oba mi
Isegun ore Re

2. Jesu t’o s’eru wa d’ayo
T’o mu ‘banuje tan
Orin ni l’eti elese
Iye at’ilera

3. O s’egun agbara ese
O da onde sile
Eje Re le w’eleri mo
Eje Re seun fun mi

4. O soro, oku gbohun Re
O gba emi titun
Onirobinuje y’ayo
Otosi si gbagbo

5. Odi, e k’orin iyin Re
Aditi gbohun Re
Afoju Olugbala de
Ayaro fo f’ayo

5. Baba mi at’Olorun mi
Fun mi n’iranwo Re
Kin le ro ka gbogbo aiye
Ola Oruko Re

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *