E Yo Ninu Oluwa, E Yo (Yoruba Hymns)

E Yo Ninu Oluwa, E Yo

1.E yo ninu Oluwa, E yo
Eyin t’okan re se dede
Eyin t’o ti yan Oluwa
L’ibanuje ati aro lo.

Egbe
E yo, e yo, E yo nin’Oluwa e yo
E yo, E yo E yo nin’Oluwa e yo.

2.E yo, to r’oun l’Oluwa
L’aye ati l’orun pelu
Oro re bor’ohun gbogbo
O l’agbara l’ati gbala.

3. Gba t’a ba n ja ija rere
Ti ota fere bori yin
Ogun Olorun t’a ko ri
Poju awon ota yin lo.

4.B’okunkun ti le yi o ka
Pelu isudede gbogbo
Mase je k’Okan re damu
Sa gbekel’Oluwa d’opin.

5.E yo ninu Oluwa, e yo
E k’orin iyin re kikan
Fi duru ati ohun ko
Halleluyah l’ohun goro.

Other Yoruba Hymns Lyrics

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *