E wole f’oba Ologo julo (Yoruba Hymn)

1. E wole f’oba Ologo julo
E korin ipa ati ife Re
Alabo wa ni, at’Eni igbani
O ngbe ‘nu ogo Eleru ni iyin

2. E so t’ipa Re, E so t’ore Re
‘Mole l’aso Re gobi Re orun
Ara tin san ni keke ‘binu Re je
Ipa-ona Re ni A ko si le mo

3. Aiye yi pelu Ekun ‘yanu Re
Olorun, agbara Re lo da won
Ofi idi re mule, ko si le yi
O si f’okun se Aso igunwa Re

4. Enu ha le so Ti itoju Re
Ninu afefe, ninu imole
Itoju Re wan nin’odo ti o nsan
O si wa ninu iri ati ojo

5. Awa erupe, Aw’alailera
‘Wo l’a gbekele O ki o da ni
Anu re rorun o si le de opin
Eleda, Alabo, Olugbala wa

6. ‘Wo Alagbara, Onife julo
B’awon Angeli Ti nyin O l’oke
Be l’awa eda Re n’iwon t’a le se
A o ma juba Re, A o ma yin O.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *