Apata Ayeraye (Yoruba Hymns)

Apata Ayeraye

Apata ayeraye
Se ibi isadi mi;
Je ki omi oun eje,
T’o n san lati iha Re,
Se iwosan f’ese mi,
K’o si so mi di mimo.

K’ Ise ise owo mi,
Lo le mu ofin Re se;
B’ itara mi ko l’are,
T’ omije mi n san titi;
Won ko to fun etutu,
‘Wo nikan l’o le gbala.

Ko s’ohun ti mo mu wa,
Mo ro mo agbelebu;
Mo wa, k’o d’aso bo mi,
Mo n wo o fun iranwo;
Mo wa sib’ orisun ni,
We mi, Olugbala mi.

‘Gbati emi mi ba n lo,
T’iku ba p’oju mi de,
Ti mba n lo s’aye aimo,
Ti n ri o n’ite ‘dajo;
Apata ayeraye,
Se ibi isadi mi.

Other Yoruba Hymns Lyrics

1 thought on “Apata Ayeraye (Yoruba Hymns)”

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *