Skip to content
Home » Adeyinka Alaseyori – Ire Iran Lyrics

Adeyinka Alaseyori – Ire Iran Lyrics

  Lyrics for Ire Iran By Adeyinka Alaseyori

  Awon kan ku lai si imuse ileri
  Olorun mi o fe
  Awon kan feti gbo ileri titi sugbon ko pada se (Olorun)
  Ileri ti mo gbo ninu bibeli ateyi ti mo la loju ala, eyi ti mo ri ninu iran ati isotele
  Ire ire, ire iran mi oh tete se lori mi tete se, majen ku kogoo to de oo
  Ire iran se mo mi lara, iran ire jo se momi lara oo
  Ire iran, iran ire tete se

  Pataki pataki ni wipe imuse ileri, aikamoye awon ileri ti a ti feti gbo ti o ba imuse pade o
  Idaduro ileri, idaduro ala, tabi iran, o le je ki omo oloogo ko maa rare oh
  Akoko imuse ileri, otoo, ire iran se mo mi lara
  Gbogbo idile lo ni ire iran atibi iran, eee ati se tojewipe egun iran lon tele opolopo kiri
  Ire Iran mi daa oh?
  Akoko imuse to oh
  Olorun, awon ti mo forolo ton sha ogo mi logbe
  Awon ti mo gbara le to jepe egun lon fi sara
  Awon ti mo so iran fun, ti won ri iran kin to ri ti won transform eh, ti won exchange e fun omo won
  Tabi ese mi, asise mi, ese iran mi, ese awon obi mi, ese ibi ti mo gbe , Ile ti mo ko, ibi ti mo tin taja
  Gbogbo ese to lemaa da imuse iran duro, Olorun, daariji mii o
  Olorun, won loo maan dahun adura o
  Olorun, o maan dahun adura o, imuse ileri mi da o, imuse ileri mi da o
  Melo nigba too ti gbo pe o maa travel oo wo local flight ri
  Opolopo de ti ririn ajo gon lolu oba sugbon sibesibe ileri o tii se
  Melo nigba too ti gbo pe o maa loyun, oyun kan O duro ri imuse ileri lo nilo
  Melo melo ni awon odo ton lawon logo to ma gbe ile ga atorilende
  Awon ko lon rare kiri, imuse, imuse ire Iran daa o
  Aimoye ebe ikoko too ni ti iwo funraare damo ti o nilo imuse lelori mu tie ko beere sini bere imuse, beere imuse ileri ogo
  Aimoye awon omo to mowe teletele, sugbon taye pa kadara won da lojiji, omo to je akinkonju to mowe gidi o wa deni ton seru labee ero
  Iwo naa bere fun imuse ileri, bere fun imuse ileri, ise ti on se yen lopolopo la ti won fi yan ti won fi yanju, logan too dawo le, gbogbo re dojude kilode? Imuse ileri lo nilo o tin see fun odunmodun, osumosu, too Olorun lo fun imuse ileri ani agbejoro nla, Jesuu loruko re oh
  Ogo ogbudo ba mi niiboji ewo mi ni, imuse ire iran o gbodo bami logba were, ewo mi ni, akoko to lati dide lori oro mi, oluwa dide
  Ire ire, ire iran mi oh tete se lori mi tete se, majen ku kogo to de oo
  Ire iran se mo mi lara, iran ire jo se momi lara oo
  Ire Iran, iran ire tete se

  Eri mi o gbodo bami niiboji oh
  Eri mi o gbodo bami niiboji oh
  Igba togo ba dee, emii mi ogbodo pin lojiji
  Eri mi o gbodo bami niiboji oh
  O ti lola ri ko loola mo, ko kinse ipin mi o, eyin teen duro lati jamibo lojiji e maa duro lasan
  Eyin teen reti ojo tee ma gbo iku mi, iku omo, iku oko, emi ni feeru feru yin, ati iyepe fun iyepe yin, ee ni rerin keyin lori oro mi, erin o ni bami nibooji oh
  Awon toon womi looke ton fe kin jabo, awon ton reti ipadabo olowo si talaka lori mi ewo ni, erii, gbo nigbati imuse ba de, oogbudo ba mi niiboji o
  Ti eri ba de tan, ti iranlowo ba de, ti igbedide ba de ati idahun adura, won o ni fimi piitan ogo, won o ni fimi piitan buburu ninu ogo, eriii, erii, ogbudo ba mi niiboji o
  Oon logo lowo nikubade kin se ipin re, awon omo to maan se fun e je won o ni da emii won legbodo lojiji lori oro re, ogo tolorun fi ta o loore, oo ni fowo gbomo sin oh
  Eri oogbudo bami niiboji o , nigba teri ba dee tan ti ogo ba de tan Alleluia lorin mi, Alleluia lorin mi, Alleluiaa konitan, leenu mi si oo o, iwo too gba kile mi dahoro titilailai, Alleluia lorin mi si o
  Nwo ma korin wipe, igbakan rii mon toro je, igbakan rii moon fogo rare, lojo ti mo ti mo Oloodumare, laye mi yipada, Igba mi dotun ninu re, lojo ti mo ti moo Oloodumare laye mi yipada, o yipada sii rere.

  Other Adeyinka Alaseyori Lyrics [display-posts category=”Adeyinka Alaseyori” exclude_current=”true”]

  Leave a Reply

  Your email address will not be published. Required fields are marked *